Genesis 13:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lọti bá gbójú sókè, ó wo gbogbo agbègbè odò Jọdani títí dé Soari, ó rí i pé gbogbo koríko ibẹ̀ ni wọ́n tutù dáradára tí ó dàbí ọgbà OLUWA ati bí ilẹ̀ Ijipti. Ní àkókò náà, OLUWA kò tíì pa ìlú Sodomu ati Gomora run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Loti si gboju rẹ̀ si oke, o si wò gbogbo àgbegbe Jordani, pe o li omi nibi gbogbo, ki OLUWA ki o to pa Sodomu on Gomorra run, bi ọgbà OLUWA, bi ilẹ Egipti, bi iwọ ti mbọ̀wa si Soari.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lọ́tì sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọ́dánì ni omi rin dáradára bí ọgbà OLÚWA, bí ilẹ̀ Éjíbítì, ní ọ̀nà Ṣóárì. (Èyí ní ìṣáájú kí OLÚWA tó pa Ṣódómù àti Gòmórà run).