Genesis 13:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lọti bá yan gbogbo agbègbè odò Jọdani fún ara rẹ̀, ó sì lọ sí ìhà ìlà oòrùn. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe takété sí ara wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Loti yàn gbogbo àgbegbe Jordani fun ara rẹ̀; Loti si nrìn lọ si ìha ìla-õrùn: bẹ̃ni nwọn yà ara wọn, ekini kuro lọdọ ekeji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà Lọ́tì yan gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọ́dánì yìí fún ara rẹ̀, ó sì ń lọ sí ọ̀nà ìlà oòrùn. Òun àti Ábúrámù sì pínyà.