Genesis 13:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, Abramu kó àgọ́ rẹ̀ wá sí ibi igi Oaku ti Mamure, tí ó wà ní Heburoni, níbẹ̀ ni ó ti tẹ́ pẹpẹ fún OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Abramu ṣí agọ́ rẹ̀, o si wá o si joko ni igbo Mamre, ti o wà ni Hebroni, o si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀ fun OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ábúrámù kó àgọ́ rẹ̀, ó sì wá láti máa gbé lẹ́bá a igbó Mámúrè ní Hébírónì níbi tí ó tẹ́ pẹpẹ kan sí fún OLÚWA.