Genesis 13:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìjà sì ń ṣẹlẹ̀ láàrin àwọn darandaran Abramu ati àwọn ti Lọti. Ní àkókò náà, àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi ń gbé ilẹ̀ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni gbolohùn asọ̀ si wà lãrin awọn darandaran Abramu, ati awọn darandaran Loti: ati awọn ara Kenaani ati awọn enia Perissi ngbé ilẹ na ni ìgba na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èdè àìyedè sì bẹ̀rẹ̀ láàrin àwọn darandaran Ábúrámù àti ti Lọ́tì. Àwọn ará a Kénánì àti àwọn ará Pérísítì sì ń gbé ní ilẹ̀ náà nígbà náà.