Genesis 13:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Abramu bá sọ fún Lọti pé, “Má jẹ́ kí ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin èmi pẹlu rẹ, tabi láàrin àwọn darandaran mi ati àwọn tìrẹ. Ṣebí ara kan náà ni wá?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Abramu si wi fun Loti pe, Emi bẹ̀ ọ, máṣe jẹ ki gbolohùn asọ̀ ki o wà lãrin temi tirẹ, ati lãrin awọn darandaran mi, ati awọn darandaran rẹ; nitori pe ará li awa iṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábúrámù sì wí fún Lọ́tì pé, “Mo fẹ́ kí a fòpin sí èdè àìyedè tí ó wà láàrin èmi àti ìwọ àti láàrin àwọn darandaran wa, nítorí pé ẹbí ni wá.