Genesis 14:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àfonífojì Sidimu kún fún ihò tí wọ́n ti wa ọ̀dà ilẹ̀. Bí àwọn ọmọ ogun ọba Sodomu ati àwọn ọmọ ogun ọba Gomora ti ń sálọ, àwọn kan ninu wọn jìn sinu àwọn ihò náà, àwọn yòókù sá gun orí òkè lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Afonifoji Siddimu si jẹ kìki kòto ọ̀da-ilẹ; awọn ọba Sodomu ati ti Gomorra sá, nwọn si ṣubu nibẹ̀; awọn ti o si kù sálọ si ori oke.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àfonífojì Ṣídímù sì kún fún kòtò ọ̀dà-ilẹ̀, nígbà tí ọba Ṣódómù àti ọba Gòmórà sì ṣá, díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin ogun náà subú sínú àwọn kòtò náà, àwọn tókù sì sálọ sì orí òkè.