Genesis 14:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà náà ni ẹnìkan tí ó sá àsálà lójú ogun náà wá ròyìn fún Abramu, tí ó jẹ́ Heberu, tí ń gbé lẹ́bàá igi Oaku, ní igbó Mamure, ará Amori. Mamure ati àwọn arakunrin rẹ̀ Eṣikolu ati Aneri bá Abramu dá majẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnikan ti o sá asalà de, o si rò fun Abramu Heberu nì; on sa tẹdo ni igbo Mamre ara Amori, arakunrin Eṣkoli ati arakunrin Aneri: awọn wọnyi li o mba Abramu ṣe pọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnìkan tí ó sá àsálà sì wá ròyìn fún Ábúrámù, ará Ébérù. Ábúrámù sá ti tẹ̀dó sí igbó igi Óákù tí ó jẹ́ ti Mámúrè ará Ámórì, arákùnrin Ésíkólì àti Ánérì: àwọn ẹni tí ó ń bá Ábúrámù ní àṣepọ̀.