Genesis 14:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Abramu ń pada bọ̀, lẹ́yìn tí ó ti ṣẹgun Kedorilaomeri ati àwọn ọba tí wọ́n jọ pa ìmọ̀ pọ̀, ọba Sodomu jáde lọ pàdé rẹ̀ ní àfonífojì Ṣafe (tí ó tún ń jẹ́, àfonífojì ọba).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba Sodomu si jade lọ ipade rẹ̀ li àbọ iṣẹgun Kedorlaomeri ati awọn ọba ti o pẹlu rẹ̀, li afonifoji Ṣafe, ti iṣe Afonifoji Ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Ábúrámù ti ṣẹ́gun Kedolaómérì àti àwọn ọba tí ó pẹ̀lú rẹ̀, ọba Ṣódómù lọ pàdé e rẹ̀ ní àfonífojì Ṣáfè (èyí tí ó túmọ̀ sí Àfonífojì ọba).