Genesis 14:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọdún kẹrinla, Kedorilaomeri ati àwọn ọba tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀ wá, wọ́n ṣẹgun Refaimu tí ó wà ní Aṣiterotu Kanaimu. Bákan náà, wọ́n ṣẹgun àwọn Susimu tí wọ́n wà ní Hamu, àwọn Emimu tí wọ́n wà ní Ṣafe-kiriataimu,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọdún kẹrinla ni Kedorlaomeri, wá ati awọn ọba ti o wà pẹlu rẹ̀, nwọn kọlu awọn Refaimu ni Aṣteroti-Karnaimu, ati awọn Susimu ni Hamu, ati awọn Emimu ni pẹtẹlẹ Kiriataimu,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọdún kẹrìnlá, ni Kédóláómérì àti àwọn ọba tí wọ́n ti jọ ni májẹ̀mú àṣepọ̀ wá, wọ́n sígun, wọ́n sì ṣẹ́gun ara Ráfáímù ní Aṣilerótì-Kánáímù, àwọn ará Ṣúsítù ni Ámù, àwọn ará Émímù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kiriátaímù,