Genesis 14:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà ni ọba Sodomu, ati ọba Gomora jáde lọ, pẹlu ọba Adima, ọba Seboimu, ati ọba Bela, (tí ó tún ń jẹ́, Soari). Wọ́n pa ogun wọn pọ̀ ní àfonífojì Sidimu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba Sodomu si jade, ati ọba Gomorra, ati ọba Adma, ati ọba Seboimu, ati ọba Bela, (eyini ni Soari;) nwọn si tẹgun si ara wọn li afonifoji Siddimu;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ọba Ṣódómù, ọba Gòmórà, ọba Ádímà, ọba Ṣébóímù àti ọba Bélà (èyí ni Ṣóárì), kó àwọn ọmọ ogun wọn, wọ́n sì pa ibùdó-ogun wọn sí àfonífojì Ṣídímù,