Genesis 15:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà ni OLUWA sọ fún un pé, “Mọ̀ dájúdájú pé àwọn ọmọ rẹ yóo lọ gbé ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiwọn, wọn yóo di ẹrú níbẹ̀, àwọn ará ibẹ̀ yóo sì mú wọn sìn fún irinwo (400) ọdún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wi fun Abramu pe, Mọ̀ nitõtọ pe irú-ọmọ rẹ yio ṣe alejo ni ilẹ ti ki iṣe ti wọn, nwọn o si sìn wọn, nwọn o si jẹ wọn ni íya ni irinwo ọdún;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni OLÚWA wí fún un pé, “Mọ èyí dájú pé, àwọn ìran rẹ yóò ṣe àtìpó ní orílẹ̀ èdè tí kì í ṣe ti wọn, a ó kó wọn lẹ́rú, a ó sì jẹ wọ́n ní ìyà fún irínwó ọdún (400).