Genesis 15:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA dá a lóhùn, ó ní, “Mú ẹgbọ̀rọ̀ abo mààlúù ọlọ́dún mẹta kan, ati ewúrẹ́ ọlọ́dún mẹta kan, ati àgbò ọlọ́dún mẹta kan, ati àdàbà kan ati ọmọ ẹyẹlé kan wá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun u pe, Mu ẹgbọrọ malu ọlọdun mẹta fun mi wá, ati ewurẹ ọlọdun mẹta, ati àgbo ọlọdun mẹta, ati oriri kan, ati ọmọ ẹiyẹle kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, OLÚWA wí fún-un pé, “Mú abo màlúù, ewúrẹ́ àti àgbò ọlọ́dún mẹ́tamẹ́ta wá, àti àdàbà kan àti ọmọ ẹyẹlé kan.”