Genesis 16:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sarai bá sọ fún Abramu pé, “Ibi tí Hagari ń ṣe sí mi yìí yóo dà lé ọ lórí. Èmi ni mo fa ẹrubinrin mi lé ọ lọ́wọ́, nígbà tí ó rí i pé òun lóyún tán, mo wá di ẹni yẹ̀yẹ́ lójú rẹ̀. OLUWA ni yóo ṣe ìdájọ́ láàrin èmi pẹlu rẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sarai si wi fun Abramu pe, Ẹbi mi wà lori rẹ: emi li o fi ọmọbinrin ọdọ mi fun ọ li àiya; nigbati o si ri pe on loyun, mo di ẹ̀gan li oju rẹ̀: ki OLUWA ki o ṣe idajọ lãrin temi tirẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ṣáráì wí fún Ábúrámù pé, “Ìwọ ni ó jẹ́ kí ẹ̀gbin yìí máa jẹmí, mo fa ọmọ ọ̀dọ̀ mi lé ọ lọ́wọ́, nígbà tí ó sì rí i pé òun lóyún, mo di ẹni ẹ̀gàn ní ojú rẹ̀. Kí OLÚWA kí ó ṣe ìdájọ́ láàrin èmi àti ìwọ.”