Genesis 16:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Abramu dá a lóhùn pé, “Ṣebí ìkáwọ́ rẹ ni ẹrubinrin rẹ wà, ṣe é bí ó bá ti wù ọ́.” Sarai bá bẹ̀rẹ̀ sí fòòró ẹ̀mí Hagari, Hagari sì sá kúrò nílé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Abramu wi fun Sarai pe, Wò o, ọmọbinrin ọdọ rẹ wà li ọwọ́ rẹ: fi i ṣe bi o ti tọ́ li oju rẹ. Nigbati Sarai nfõró rẹ̀, o sá lọ kuro lọdọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábúrámù dáhùn pé, “Ìwọ ló ni ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣe ohunkóhun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ sí i.” Nígbà náà ni Ṣáráì fi ìyà jẹ ẹ́, ó sì sá lọ.