Genesis 17:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọlọrun dá a lóhùn, pé, “Rárá o, àní, Sara, aya rẹ, yóo bí ọmọkunrin kan fún ọ, o óo sọ ọmọ náà ní Isaaki. N óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ayérayé fún atọmọdọmọ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọlọrun si wipe, Sara, aya rẹ, yio bí ọmọkunrin kan fun ọ nitõtọ; iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Isaaki: emi o fi idi majẹmu mi mulẹ pẹlu rẹ̀, ni majẹmu aiyeraiye, ati pẹlu irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ọlọ́run wí pé, “Mo gbọ́, ṣùgbọ́n Ṣárà aya rẹ̀ yóò bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ísáákì, èmi yóò fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní májẹ̀mú ayérayé àti àwọn irú ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.