Genesis 18:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀kan ninu àwọn àlejò náà wí pé, “Dájúdájú, n óo pada tọ̀ ọ́ wá ní ìwòyí ọdún tí ń bọ̀, Sara, aya rẹ yóo bí ọmọkunrin kan.” Sara fetí mọ́ ògiri lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ lẹ́yìn ibi tí àwọn àlejò náà wà, ó ń gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Emi o si tun pada tọ̀ ọ wá nitõtọ ni iwoyi amọ́dun; si kiyesi i, Sara aya rẹ yio li ọmọkunrin kan. Sara si gbọ́ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ti o wà lẹhin ọkunrin na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni OLÚWA wí fún un pé, “Ṣárà aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.” Sárà sì ń dẹtí gbọ́ láti ẹnu ọ̀nà àgọ́ tí ó wà lẹ́yìn wọn.