Genesis 18:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ó ti gbójú sókè, bẹ́ẹ̀ ni ó rí àwọn ọkunrin mẹta kan, wọ́n dúró ní ọ̀kánkán níwájú rẹ̀. Bí ó ti rí wọn, ó sáré lọ pàdé wọn, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀ láti kí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si gbé oju rẹ̀ soke, o wò, si kiyesi i, ọkunrin mẹta duro li ẹba ọdọ rẹ̀: nigbati o si ri wọn, o sure lati ẹnu-ọ̀na agọ́ lọ ipade wọn, o si tẹriba silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábúráhámù gbójú sókè, ó sì rí àwọn ọkùnrin mẹ́ta tí wọn dúró nítòsí rẹ̀. Nígbà tí ó rí wọn, ó sáré láti lọ pàdé wọn, ó sì tẹríba bí ó ti ń kí wọn.