Genesis 18:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí á má rí i pé o ṣe irú ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀! Kí o pa olódodo run pẹlu àwọn eniyan burúkú? Ṣé kò ní sí ìyàtọ̀ láàrin ìpín àwọn eniyan burúkú ati ti àwọn olódodo ni? A kò gbọdọ̀ gbọ́ ọ. Ìwọ onídàájọ́ gbogbo ayé kò ha ní ṣe ẹ̀tọ́ bí?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O ha dára, ti iwọ o fi ṣe bi irú eyi, lati run olododo pẹlu enia buburu; ti awọn olododo yio fi dabi awọn enia buburu, o ha dára: Onidajọ gbogbo aiye ki yio ha ṣe eyi ti o tọ́?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò jẹ́ rí bẹ́ẹ̀! Dájúdájú Ìwọ kì yóò ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀, láti pa olódodo pẹ̀lú àwọn ènìyàn rere àti àwọn ènìyàn búburú. Dájúdájú Ìwọ kì yóò ṣe èyí tí ó tó bi?”