Genesis 18:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn, ó ṣeéṣe pé aadọta tí mo wí lè dín marun-un, ṣé nítorí eniyan marun-un tí ó dín, o óo pa ìlú náà run?” OLUWA dáhùn pé, “Bí mo bá rí olódodo marundinlaadọta n kò ní pa ìlú náà run.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bọya marun a dín ninu ãdọta olododo na: iwọ o ha run gbogbo ilu na nitori marun? On si wipe, Bi mo ba ri marunlelogoji nibẹ̀, emi ki yio run u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
bí ó bá ṣe pe olódodo márùn-dín-làádọ́ta (45) ni ó wà nínú ìlú, Ìwọ yóò ha pa ìlú náà run nítorí ènìyàn márùn-ún bí?” OLÚWA dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo márùn-dín-láàádọ́ta nínú rẹ̀.”