Genesis 18:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó tún dáhùn pé “Jọ̀wọ́ dárí àfojúdi mi jì mí nítorí ọ̀rọ̀ mi, bí a bá rí ogún eniyan ńkọ́?” OLUWA tún dáhùn pé, “Nítorí ti ogún eniyan, n kò ní pa á run.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Wò o na, emi ti dawọle e lati ba OLUWA sọ̀rọ: bọya a o ri ogun nibẹ̀. On si wipe, Emi ki yio run u nitori ogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábúráhámù wí pé, “Níwọ̀n bí mo ti ní ìgboyà láti bá OLÚWA sọ̀rọ̀ báyìí, jẹ́ kí n tẹ̀ṣíwájú. Bí o bá ṣe pé olódodo ogún péré ni ó wà nínú ìlú náà ńkọ́?” OLÚWA sì dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa á run nítorí ogún ènìyàn náà.”