Genesis 19:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà ni àwọn angẹli meji náà dé ìlú Sodomu, Lọti sì jókòó ní ẹnubodè ìlú náà. Bí ó ti rí wọn, ó dìde lọ pàdé wọn, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀ láti kí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
AWỌN Angeli meji si wá si Sodomu li aṣalẹ; Loti si joko li ẹnu-bode Sodomu: bi Loti si ti ri wọn, o dide lati pade wọn: o si dojubolẹ;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àsáálẹ́, àwọn ańgẹ́lì méjì sì wá sí ìlú Ṣódómù, Lọ́tì sì jókòó ní ẹnu ibodè ìlú. Bí ó sì ti rí wọn, ó sì dide láti pàdé wọn, ó kí wọn, ó sí foríbalẹ̀ fún wọn.