Genesis 19:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
nítorí pé a ti ṣetán láti pa ìlú yìí run, nítorí ẹ̀sùn tí wọ́n fi ń kan àwọn ará ìlú yìí ti pọ̀ níwájú OLUWA, OLUWA sì ti rán wa láti pa á run.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori awa o run ibi yi, nitori ti igbe wọn ndi pupọ̀ niwaju OLUWA; OLUWA si rán wa lati run u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nítorí a ó pa ìlú yìí run, nítorí igbe iṣẹ́ búrurú wọn ń dí púpọ̀ níwájú OLÚWA, OLÚWA sì rán wa láti pa á run.”