Genesis 19:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú, àwọn angẹli náà rọ Lọti pé, “Dìde, mú aya rẹ ati àwọn ọmọ rẹ mejeeji tí wọ́n wà níhìn-ín kí o sì jáde, kí o má baà parun pẹlu ìlú yìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ọ̀yẹ si nla, nigbana li awọn angeli na le Loti ni ire wipe, Dide, mu aya rẹ, ati awọn ọmọbinrin rẹ mejeji ti o wà nihin; ki iwọ ki o má ba run ninu ìya ẹ̀ṣẹ ilu yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àfẹ̀mọ́jú, àwọn ańgẹ́lì náà rọ Lọ́tì pé, “Ṣe wéré, mú aya rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì tí ó wà níhìnín, àìṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò parun pẹ̀lú ìlú yìí nígbà tí wọ́n bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”