Genesis 19:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n kó wọn jáde tán, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí yín; ẹ má ṣe wo ẹ̀yìn rárá, ẹ má sì ṣe dúró níbikíbi ní àfonífojì yìí, ẹ sá gun orí òkè lọ, kí ẹ má baà parun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe nigbati nwọn mu wọn jade sẹhin odi tan, li o wipe, Sá asalà fun ẹmi rẹ; máṣe wò ẹhin rẹ, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe duro ni gbogbo pẹtẹlẹ; sá asalà lọ si ori oke, ki iwọ ki o má ba ṣegbe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní kété tí wọ́n mú wọn jáde tán, ọ̀kan nínú àwọn Ańgẹ́lì náà wí fún wọn pé, “Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí ti yín, ẹ má ṣe wẹ̀yìn, orí òkè ni kí ẹ sá lọ, ẹ má ṣe dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àìṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin yóò ṣègbé!”