Genesis 19:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọlọrun ranti Abrahamu, nígbà tí ó pa àwọn ìlú tí ó wà ní àfonífojì náà, níbi tí Lọti ń gbé run, ó yọ Lọti jáde kúrò ninu ìparun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe nigbati Ọlọrun run ilu àgbegbe wọnni ni Ọlọrun ranti Abrahamu, o si rán Loti jade kuro lãrin iparun na, nigbati o run ilu wọnni ninu eyiti Loti gbé ti joko.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́run sì rántí Ábúráhámù, nígbà tí ó run ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì tan, ó sì mú Lọ́tì jáde kúrò láàrin ìparun náà, tí ó kọ lu ìlú tí Lọ́tì ti gbé.