Genesis 19:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ó rọ̀ wọ́n gidigidi, wọ́n bá yà sí ilé rẹ̀, ó se àsè fún wọn, ó ṣe àkàrà tí a kò fi ìwúkàrà sí, wọ́n sì jẹun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si rọ̀ wọn gidigidi; nwọn si yà tọ̀ ọ, nwọn si wọ̀ inu ile rẹ̀; o si sè àse fun wọn, o si dín àkara alaiwu fun wọn, nwọn si jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Lọ́tì rọ̀ wọ́n gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n gbà láti bá a lọ sì ilé. Ó sì ṣe oúnjẹ fún wọn, ó ṣe Búrẹ́dì aláìwú wọ́n sì jẹ ẹ́.