Genesis 19:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó yá, Lọti jáde kúrò ní Soari, nítorí ẹ̀rù ń bà á láti máa gbé ibẹ̀, òun ati àwọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeeji bá kó lọ sí orí òkè, wọ́n sì ń gbé inú ihò kan níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Loti si jade kuro ni Soari: o si ngbé ori oke, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeji pẹlu rẹ̀; nitoriti o bẹ̀ru ati gbé Soari: o si ngbé inu ihò, on ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lọ́tì àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjèèjì sì kúrò ní Sóárì, wọ́n sì ń lọ gbé ní orí òkè ní inú ihò-àpáta, nítorí ó bẹ̀rù láti gbé ní ìlú Sóárì.