Genesis 19:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ keji, èyí àkọ́bí sọ fún àbúrò pé, “Èmi ni mo sùn lọ́dọ̀ baba wa lánàá, jẹ́ kí á tún mú kí ó mu ọtí àmupara lálẹ́ òní, kí ìwọ náà lè wọlé tọ̀ ọ́ lọ, kí ó lè bá ọ lòpọ̀, kí á sì lè bímọ nípasẹ̀ baba wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, ni ijọ́ keji, ni ẹgbọn wi fun aburo pe, kiyesi i, emi sùn tì baba mi li oru aná: jẹ ki a si mu u mu ọti-waini li oru yi pẹlu: ki iwọ ki o si wọle, ki o si sùn tì i, ki awa ki o le ni irú-ọmọ lati ọdọ baba wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kejì èyí ẹ̀gbọ́n wí fún àbúrò rẹ̀ pé, “Ní àná mo sùn ti bàbá mi. Jẹ́ kí a tún wọlé tọ̀ ọ́, kí a lè ní irú ọmọ láti ọ̀dọ̀ baba wa.”