Genesis 19:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ wò ó, mo ní àwọn ọmọbinrin meji tí wọn kò tíì mọ ọkunrin, ẹ jẹ́ kí n kó wọn jáde fún yín, kí ẹ ṣe wọ́n bí ó ti wù yín, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi àwọn ọkunrin wọnyi sílẹ̀, nítorí pé inú ilé mi ni wọ́n wọ̀ sí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i nisisiyi, emi li ọmọbinrin meji ti kò ti imọ̀ ọkunrin: emi bẹ̀ nyin, ẹ jẹ ki nmu wọn jade tọ̀ nyin wá, ki ẹnyin ki o si fi wọn ṣe bi o ti tọ́ loju nyin: ṣugbọn awọn ọkunrin wọnyi ṣa ni ki ẹ má ṣe ni nkan; nitorina ni nwọn sa ṣe wá si abẹ orule mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
kíyèsí i, mo ní ọmọbìnrin méjì tí kò mọ ọkùnrin rí, ẹ jẹ́ kí n mú wọn tọ̀ yín wá kí ẹ sì ṣe ohun tí ẹ fẹ́ pẹ̀lú wọn. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ṣe àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ní ibi kan nítorí wọ́n wá wọ̀ lábẹ́ ààbò ní ilé mi.”