Genesis 2:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun bu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ gbogbo ẹranko ati gbogbo ẹyẹ. Ó kó wọn tọ ọkunrin náà wá, láti mọ orúkọ tí yóo sọ olukuluku wọn. Orúkọ tí ó sì sọ wọ́n ni wọ́n ń jẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati inu ilẹ li OLUWA Ọlọrun si ti dá ẹranko igbẹ gbogbo, ati ẹiyẹ oju-ọrun gbogbo; o si mu wọn tọ̀ Adamu wá lati wò orukọ ti yio sọ wọn; orukọkorukọ ti Adamu si sọ olukuluku ẹda alãye, on li orukọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn tí OLÚWA Ọlọ́run ti dá àwọn ẹranko inú igbó àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀, Ó sì kó wọn tọ ọkùnrin náà wá láti wo orúkọ tí yóò sọ wọ́n; orúkọ tí ó sì sọ gbogbo ẹ̀dá alààyè náà ni wọ́n ń jẹ́.