Genesis 2:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà náà ni OLUWA Ọlọrun bù ninu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ eniyan. Ó mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, eniyan sì di ẹ̀dá alààyè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA Ọlọrun si fi erupẹ ilẹ mọ enia; o si mí ẹmí ìye si ihò imu rẹ̀; enia si di alãye ọkàn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA Ọlọ́run sì mọ ènìyàn láti ara erùpẹ̀ ilẹ̀, ó si mí èémí sí ihò imú rẹ̀, èémí ìyè, ènìyàn sì di ẹ̀dá alààyè.