Genesis 20:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Abimeleki mú aguntan ati mààlúù ati ẹrukunrin ati ẹrubinrin, ó kó wọn fún Abrahamu, ó sì dá Sara, aya rẹ̀, pada fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Abimeleki si mu agutan, ati akọmalu, ati iranṣẹkunrin, ati iranṣẹbinrin, o si fi wọn fun Abrahamu, o si mu Sara, aya rẹ̀, pada fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ábímélékì mú àgùntàn àti màlúù wá, àti ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ó sì kó wọn fún Ábúráhámù, ó sì dá Sárà aya rẹ̀ padà fún un.