Genesis 20:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó wí fún Sara náà pé, “Mo ti kó ẹgbẹrun (1,000) owó fadaka fún arakunrin rẹ, èyí ni láti wẹ̀ ọ́ mọ́ lójú gbogbo àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ, nisinsinyii, o ti gba ìdáláre lójú gbogbo eniyan.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun Sara pe, Kiyesi i, mo fi ẹgbẹrun ìwọn fadaka fun arakunrin rẹ: kiyesi i, on ni ibojú fun ọ fun gbogbo awọn ti o wà lọdọ rẹ, ati niwaju gbogbo awọn ẹlomiran li a da ọ lare.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábímélékì sì wí fún Ṣárà pé, “Mo fi ẹgbẹ̀rún owó ẹyọ fàdákà fún arákùnrin rẹ. Éyí ni owó ìtanràn ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ níwájú gbogbo ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ àti pé, a dá ọ láre pátapáta.”