Genesis 20:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Abimeleki yára dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó pe gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ jọ, ó ro gbogbo nǹkan wọnyi fún wọn, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina Abimeleki dide ni kutukutu owurọ̀, o si pè gbogbo awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, o si wi gbogbo nkan wọnyi li eti wọn: ẹ̀ru si bà awọn enia na gidigidi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, Ábímélékì pe gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀. Nígbà tí ó sì ṣọ gbogbo ohun tí ó sẹlẹ̀ fún wọn, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi.