Genesis 21:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó lọ jókòó ní òkèèrè, ó takété sí i, ó tó ìwọ̀n ibi tí ọfà tí eniyan bá ta lè balẹ̀ sí, nítorí ó wí ninu ara rẹ̀ pé, “Má jẹ́ kí n wo àtikú ọmọ mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si lọ, o joko kọju si i, li ọ̀na jijìn rére, o tó bi itafasi kan: nitori ti o wipe, Ki emi má ri ikú ọmọ na. O si joko kọju si i, o gbé ohùn rẹ̀ soke, o nsọkun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì lọ, ó sì jókòó nítòòsí ibẹ̀, níwọ̀n bí ìtafà (bí i ogójì míta), nítorí, ó rò ó nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi kò fẹ́ wo bí ọmọ náà yóò ṣe kú.” Bí ó sì ti jókòó sí tòòsí ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún.