Genesis 21:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ó ṣe jókòó tí ó takété sí ọmọ náà, ọmọ fi igbe ta, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Ọlọrun gbọ́ igbe ọmọ náà, angẹli Ọlọrun bá ké sí Hagari láti ọ̀run wá, ó bi í pé, “Kí ni ó ń dààmú ọkàn rẹ, Hagari? Má bẹ̀rù, nítorí Ọlọrun ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí ó wà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọlọrun si gbọ́ ohùn ọmọdekunrin na: angeli Ọlọrun si pè Hagari lati ọrun wá, o bi i pe, Kili o ṣe ọ, Hagari? máṣe bẹ̀ru; nitori ti Ọlọrun ti gbọ́ ohùn ọmọdekunrin na nibiti o gbé wà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́run gbọ́ ohun ẹkún náà, Ańgẹ́lì Ọlọ́run sì pe Ágárì láti ọ̀run, ó sì wí fun un pé, “Ágárì, kín ni ó ṣe ọ́? Má bẹ̀rù nítorí OLÚWA ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí o tẹ́ ẹ sí.