Genesis 21:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọlọrun wà pẹlu ọmọ náà, ó dàgbà, ó ń gbé ninu aginjù, ó sì mọ ọfà ta tóbẹ́ẹ̀ tí ó di atamátàsé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọlọrun si wà pẹlu ọmọdekunrin na; o si dàgba, o si joko ni ijù, o di tafatafa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú ọmọ náà bí ó ti ń dàgbà, ó ń gbé nínú ìjù, ó sì di tafàtafà.