Genesis 22:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Angẹli náà wí fún un pé, “Má ṣe pa ọmọ náà rárá, má sì ṣe é ní ohunkohun, nítorí pé nisinsinyii mo mọ̀ dájú pé o bẹ̀rù Ọlọrun, nígbà tí o kò kọ̀ láti fi ọmọ rẹ kan ṣoṣo tí o bí rúbọ sí èmi Ọlọrun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Máṣe fọwọkàn ọmọde nì, bẹ̃ni iwọ kó gbọdọ ṣe e ni nkan: nitori nisisiyi emi mọ̀ pe iwọ bẹ̀ru Ọlọrun, nigbati iwọ kò ti dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kanṣoṣo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ańgẹ́lì OLÚWA sì wí pé, “Má ṣe fọwọ́ kan ọmọ náà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣe é ni ohun kan. Nísinsin yìí ni mo mọ̀ pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, nítorí pé ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan soso dùn mi.”