Genesis 22:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà ni Abrahamu ṣe sọ ibẹ̀ ní “OLUWA yóo pèsè,” bí wọ́n ti ń wí títí di òní, pé, “Ní orí òkè OLUWA ni yóo ti pèsè.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Abrahamu si pè orukọ ibẹ̀ na ni Jehofajire: bi a ti nwi titi di oni yi, Li oke OLUWA li a o gbé ri i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábúráhámù sì pe orúkọ ibẹ̀ ni, OLÚWA yóò pèṣè (Jìhófà Jirè). Bẹ́ẹ̀ ni a sì ń wí títí di òní olónìí pé, “Ní orí òkè OLÚWA, ni a ó ti pèsè.”