Genesis 22:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Abrahamu bá pada tọ àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ lọ, wọ́n bá jọ gbéra, wọ́n pada lọ sí Beeriṣeba, Abrahamu sì ń gbé ibẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Abrahamu si pada tọ̀ awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ lọ, nwọn si dide, nwọn si jùmọ lọ si Beer-ṣeba; Abrahamu si joko ni Beer-ṣeba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ábúráhámù padà tọ àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ lọ. Gbogbo wọn sì padà lọ sí Báá-Ṣébà Ábúráhámù sì dúró ní Báá-Ṣébà.