Genesis 22:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọlọrun ní, “Mú Isaaki ọmọ rẹ kan ṣoṣo tí o fẹ́ràn, kí o lọ sí ilẹ̀ Moraya, kí o sì fi ọmọ náà rú ẹbọ sísun lórí ọ̀kan ninu àwọn òkè tí n óo júwe fún ọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun u pe, Mu ọmọ rẹ nisisiyi, Isaaki, ọmọ rẹ na kanṣoṣo, ti iwọ fẹ́, ki iwọ ki o si lọ si ilẹ Moria; ki o si fi i rubọ sisun nibẹ̀ lori ọkan ninu oke ti emi o sọ fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́run sì wí pé, “Mú ọmọ rẹ, àní Ísáakì ọmọ rẹ kan ṣoṣo o nì, tí ìwọ fẹ́ràn, lọ sí ilẹ̀ Móráyà, kí o sì fi rúbọ ṣíṣun níbẹ̀ lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè tí èmi yóò sọ fún ọ”