Genesis 22:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Isaaki bá pe Abrahamu, baba rẹ̀, ó ní, “Baba mi.” Baba rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Kí ni, ọmọ mi?” Isaaki ní, “Wò ó, a rí iná ati igi, àgbò tí a óo fi rú ẹbọ sísun dà?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Isaaki si sọ fun Abrahamu baba rẹ̀, o si wipe, Baba mi: on si wipe, Emi niyi, ọmọ mi. On si wipe, Wò iná on igi; ṣugbọn nibo li ọdọ-agutan ẹbọ sisun na gbé wà?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ísáákì sì sọ fún Ábúráhámù baba rẹ̀ wí pé, “Baba mi.” Ábúráhámù sì da lóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi.” Ísáákì sì tún wí pé, “Wò ó iná àti igi nìyí, ṣùgbọ́n níbo ni ọ̀dọ́ àgùntàn fún ẹbọ sísun náà wà?”