Genesis 22:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n dé ibi tí Ọlọrun júwe fún Abrahamu, ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀, ó to igi sórí pẹpẹ náà, ó di Isaaki ọmọ rẹ̀ tọwọ́ tẹsẹ̀, ó bá gbé e ka orí igi lórí pẹpẹ tí ó tẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si de ibi ti Ọlọrun ti wi fun u; Abrahamu si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, o si to igi rere, o si dì Isaaki ọmọ rẹ̀, o si dá a bulẹ li ori pẹpẹ lori igi na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọn sì dé ibi tí Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù, ó mọ pẹpẹ kan, ó sì to igiọ lé e lórí, ó sì di Ísáákì ọmọ rẹ̀, ó sì da dùbúlẹ̀ lórí pẹpẹ náà.