Genesis 23:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Rárá o! oluwa mi, gbọ́, mo fún ọ ní ilẹ̀ náà, ati ihò tí ó wà ninu rẹ̀, lójú gbogbo àwọn eniyan mi ni mo sì ti fún ọ, lọ sin aya rẹ sibẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃kọ, Oluwa mi, gbọ́ ti emi, mo fi oko na fun ọ, ati ihò ti o wà nibẹ̀, mo fi fun ọ: li oju awọn ọmọ awọn enia mi ni mo fi i fun ọ: sin okú rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
pé, “Rárá, Olúwa mi, Gbọ́ tèmi; mo fún ọ ní ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà níbẹ̀. Mo fún ọ níwájú gbogbo àwọn ènìyàn mi. Sin òkú rẹ ṣíbẹ̀.”