Genesis 23:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó bá sọ fún Efuroni lójú gbogbo wọn, ó ní, “Ṣugbọn, bí ó bá ti ọkàn rẹ wá, fún mi ní ilẹ̀ náà, kí n sì san owó rẹ̀ fún ọ. Gbà á lọ́wọ́ mi, kí n lè lọ sin aya mi sibẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun Efroni, li eti awọn enia ilẹ na pe, Njẹ bi iwọ o ba fi i fun mi, emi bẹ̀ ọ, gbọ́ ti emi: emi o san owo oko na fun ọ; gbà a lọwọ mi, emi o si sin okú mi nibẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún Éfúrónì lójú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ bá fẹ́, gbọ́ tèmi, èmi yóò san owó ilẹ̀ náà, gbà á lọ́wọ́ mi kí n lè sin òkú mi ṣíbẹ̀.”