Genesis 23:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ Efuroni ní Makipela, tí ó wà ní apá ìhà ìlà oòrùn Mamure ṣe di ti Abrahamu, ati ihò tí ó wà ninu ilẹ̀ náà, ati gbogbo igi tí ó wà ninu rẹ̀ jákèjádò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oko Efroni ti o wà ni Makpela, ti o wà niwaju Mamre, oko na, ati ihò ti o wà ninu rẹ̀, ati gbogbo igi ti o wà ni oko na, ti o wà ni gbogbo ẹba rẹ̀ yika, li a ṣe daju,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni ilẹ̀ Éfúrónì tí ó wà ni Mákípélà nítòòsí Mámúrè-ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ àti gbogbo igi tí ó wà nínú ilẹ̀ náà ni a ṣe ètò rẹ̀ dájú,