Genesis 23:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ilẹ̀ náà ati ihò tí ó wà ninu rẹ̀ ni àwọn ará Hiti fi fún Abrahamu láti máa lò bí itẹ́ òkú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati oko na, ati ihò ti o wà nibẹ̀, li a ṣe daju fun Abrahamu, ni ilẹ isinku, lati ọwọ́ awọn ọmọ Heti wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ilẹ̀ náà àti ihò-àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni àwọn ará Hítì fi fún Ábúráhámù gẹ́gẹ́ bí ohun ìní títí láé bí ilẹ̀ ìsìnkú fún àwọn òkú tí ó bá kú fun un.