Genesis 24:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí ó tó dákẹ́ adura rẹ̀ ni Rebeka ọmọ Betueli yọ sí i pẹlu ìkòkò omi ní èjìká rẹ̀. Ọmọ Nahori ni Betueli jẹ́, tí Milika bí fún un. Nahori yìí jẹ́ arakunrin Abrahamu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, ki on to pari ọ̀rọ isọ, kiyesi i, Rebeka jade de, ẹniti a bí fun Betueli, ọmọ Milka, aya Nahori, arakunrin Abrahamu, ti on ti ladugbo rẹ̀ li ejika rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí o tó di pé, ó parí àdúrà, Rèbékà dé pẹ̀lú ìkòkò omi rẹ̀ ní èjìká rẹ̀. Ọmọ Bétúélì ni. Bétúélì yìí ni Mílíkà bí fún Náhórì arákùnrin Ábúráhámù.