Genesis 24:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọkunrin náà bá wọlé, Labani sì tú gàárì àwọn ràkúnmí rẹ̀, ó fi koríko ati oúnjẹ fún wọn. Ó fún un ní omi láti fi ṣan ẹsẹ̀ rẹ̀ ati ẹsẹ̀ àwọn ọkunrin tí wọ́n bá a wá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin na si wọle na wá; o si tú awọn ibakasiẹ, o si fun awọn ibakasiẹ, ni koriko ati sakasáka, ati omi fun u lati wẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀, ati ẹsẹ̀ awọn ọkunrin ti o pẹlu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkùnrin náà sì bá Lábánì lọ ilé, ó sì tú ẹrù orí ràkunmí rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fún wọn ni koríko àti oúnjẹ. Ó sì bu omi fún ọkùnrin náà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ láti wẹ ẹsẹ̀ wọn.