Genesis 24:40 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ó sọ fún mi pé, ‘OLUWA náà tí òun ń fi gbogbo ayé òun sìn yóo rán angẹli rẹ̀ sí mi, yóo sì ṣe ọ̀nà mi ní rere. Ó ní, mo ṣá gbọdọ̀ fẹ́ aya fún ọmọ òun láàrin àwọn eniyan òun ati ní ilé baba òun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun mi pe, OLUWA, niwaju ẹniti emi nrìn, yio rán angeli rẹ̀ pelu rẹ, yio si mu ọ̀na rẹ dara; iwọ o si fẹ́ aya fun ọmọ mi lati ọdọ awọn ibatan mi, ati lati inu ile baba mi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ó sì dáhùn wí pé, ‘OLÚWA, níwájú ẹni tí èmi ń rìn yóò rán Ańgẹ́lì rẹ̀ ṣáájú rẹ yóò sì jẹ́ kí o ṣe aṣeyọrí ní ìrìn-àjò rẹ, kí ìwọ kí ó ba le fẹ́ aya fún ọmọ mi, láàrin àwọn ìbátan mi, àti láàrin àwọn ìdílé baba mi.